Ọrọ Orúkọ (Noun)
Ọrọ Orúkọ (Noun) Ọrọ Orúkọ ni awọn ọrọ tó lè dá dúró nipo oluwa, abọ ati ẹ̀yán. i) Olùwà Olùwà ni olùṣe inu gbólóhùn. Àpẹẹrẹ: Tade je eba Femi ra ọkọ tuntun Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí, Tade ati Femi ni o je ọrọ Orúkọ nipo oluwa. ii) Abọ: Abọ ni olufaragba ohun ti oluwa n se nínu gbólóhùn. Àpẹẹrẹ:Tade je eba Femi ra ọkọ tuntun Eba ati ọkọ ni abọ nínú àpẹẹrẹ yìí iii) Ẹ̀yán: Èyán máa wáyé nígbà tí ọrọ Orúkọ meji ba tele ra won, ọrọ Orúkọ keji máa jẹ eyan. Àpẹẹrẹ: Eja alaran-an ni mo ra Baba Kemi wo bàtà tuntun Ise Síse Kọ gbólóhùn marun ki o si fala sí ọrọ Orúkọ inu rẹ