Posts

Showing posts from 2021

Ọrọ Orúkọ (Noun)

 Ọrọ Orúkọ (Noun) Ọrọ Orúkọ ni awọn ọrọ tó lè dá dúró nipo oluwa, abọ ati ẹ̀yán. i) Olùwà Olùwà ni olùṣe inu gbólóhùn.  Àpẹẹrẹ: Tade je eba Femi ra ọkọ tuntun Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí, Tade ati Femi ni o je ọrọ Orúkọ nipo oluwa. ii) Abọ: Abọ ni olufaragba ohun ti oluwa n se nínu gbólóhùn. Àpẹẹrẹ:Tade je eba Femi ra ọkọ tuntun  Eba ati ọkọ ni abọ nínú àpẹẹrẹ yìí iii) Ẹ̀yán: Èyán máa wáyé nígbà tí ọrọ Orúkọ meji ba tele ra won, ọrọ Orúkọ keji máa jẹ eyan. Àpẹẹrẹ: Eja alaran-an ni mo ra Baba Kemi wo bàtà tuntun Ise Síse Kọ gbólóhùn marun ki o si fala sí ọrọ Orúkọ inu rẹ